Esther 1:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Memkani bá dáhùn níwájú ọba ati àwọn ìjòyè pé, “Kì í ṣe ọba nìkan ni Faṣiti kò kà sí, bíkòṣe gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè ìjọba Ahasu-erusi ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Memukani si dahùn niwaju ọba ati awọn ijoye pe, Faṣti ayaba kò ṣẹ̀ si ọba nikan, ṣugbọn si gbogbo awọn ijoye, ati si gbogbo awọn enia ti o wà ni ìgberiko Ahaswerusi ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mémúkánì sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Fásítì ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan Ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba Ṣérísésì.