Esther 1:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nǹkan tí Faṣiti ṣe yìí yóo di mímọ̀ fún àwọn obinrin, àwọn náà yóo sì máa fi ojú tẹmbẹlu àwọn ọkọ wọn. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọba ṣá ti ranṣẹ sí ayaba pé kí ó wá siwaju òun rí, tí ó kọ̀, tí kò lọ.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ìwa ayaba yi yio tàn de ọdọ gbogbo awọn obinrin, tobẹ̃ ti ọkọ wọn yio di gigàn loju wọn, nigbati a o sọ ọ wi pe, Ahaswerusi ọba paṣẹ pe, ki a mu Faṣti ayaba wá siwaju rẹ̀, ṣugbọn on kò wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obínrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójúu wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ṣérísésì pàṣẹ̀ pé kí á mú ayaba Fásítì wá ṣíwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá.