Esther 1:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti òní lọ, àwọn obinrin, pàápàá àwọn obinrin Pasia ati ti Media, tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí Ayaba ṣe yóo máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí àwọn ìjòyè. Èyí yóo sì mú kí aifinipeni ati ibinu pọ̀ sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọlọla-obinrin Persia ati Media yio si ma wi bakanna li oni yi fun gbogbo awọn ijoye ọba ti nwọn gbọ́ ìwa ti ayaba hù. Bayi ni ẹ̀gan pipọ̀-pipọ̀, ati ibinu yio dide.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ yìí gan-an ni àwọn ọlọ́lá obinrin Páṣíà àti ti Médíánì tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.