Esther 1:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ṣe ọgbà náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró ati aṣọ funfun. Wọ́n fi òwú funfun ati òwú àlàárì ṣe okùn, wọ́n fi so wọ́n mọ́ òrùka fadaka, wọ́n gbé wọn kọ́ sára òpó òkúta mabu. Wúrà ati fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn àga tí ó wà ninu ọgbà. Òkúta mabu pupa ati aláwọ̀ aró ni wọ́n fi ṣe gbogbo ọ̀dẹ̀dẹ̀, tí gbogbo wọn ń dán gbinringbinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nibiti a gbe ta aṣọ àla daradara, aṣọ alaro, ati òféfe, ti a fi okùn ọ̀gbọ daradara, ati elesè aluko dimu mọ oruka fadaka, ati ọwọ̀n okuta marbili: wura ati fadaka ni irọgbọku, ti o wà lori ilẹ ti a fi okuta alabastari, marbili, ilẹkẹ daradara, ati okuta dudu tẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elésé àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mábù. Àwọn ibùṣùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mábù, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn.