Esther 1:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àṣẹ ọba ni wọ́n tẹ̀lé nípa ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Wọn kò fi ipá mú ẹnikẹ́ni, nítorí pé ọba ti pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pé ohun tí olukuluku bá fẹ́ ni kí wọn fi tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi aṣẹ si ni mimu na; ẹnikẹni kò fi ipa rọ̀ ni: nitori bẹ̃ni ọba ti fi aṣẹ fun gbogbo awọn olori ile rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣe gẹgẹ bi ifẹ olukuluku.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ.