Esther 10:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Modekai tíí ṣe Juu ni igbákejì sí Ahasu-erusi ọba. Ó tóbi, ó sì níyì pupọ láàrin àwọn Juu, nítorí pé ó ń wá ire àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ alaafia fún gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Mordekai ara Juda li o ṣe igbakeji Ahaswerusi ọba, o si tobi ninu awọn Ju, o si ṣe itẹwọgbà lọdọ ọ̀pọlọpọ ninu awọn arakunrin rẹ̀, o nwá ire awọn enia rẹ̀, o si nsọ̀rọ alafia fun gbogbo awọn iru-ọmọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Módékáì ará Júù ni ó jẹ́ igbá kejì ọba Ṣéríṣésì, ó tóbi láàrin àwọn Júù, ó sì jẹ́ ẹni iyì lọ́dọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, nítorí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn ènìyàn an rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ fún àlàáfíà gbogbo àwọn Júù.