Esther 2:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó tó àkókò fún Ẹsita, ọmọ Abihaili ẹ̀gbọ́n Modekai, láti lọ rí ọba, Ẹsita kò bèèrè nǹkankan ju ohun tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba tí ń tọ́jú àwọn ayaba, sọ fún un pé kí ó mú lọ. Ẹsita rí ojurere lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n rí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nigbati o kan Esteri, ọmọ Abihaili, arakunrin Mordekai, ẹniti o mu u ṣe ọmọ ara rẹ̀, lati wọle tọ̀ ọba lọ, on kò bère ohunkohun, bikoṣe ohun ti Hegai, ìwẹfa ọba, olutọju awọn obinrin paṣẹ. Esteri si ri ojurere lọdọ gbogbo ẹniti nwò o.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó kan Ẹ́sítà (ọmọbìnrin tí Módékáì gbà ṣe ọmọ, ọmọbìnrin arákùnrin rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Ábíháílì) láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọn kò bèrè fún ohunkóhun ju èyí tí Hégáì, ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ilé àwọn obìnrin sọ pé kí ó ṣe lọ. Ẹ́sítà sì rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó rí i.