Esther 2:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo àwọn obinrin yòókù lọ, ó sì rí ojurere ọba ju gbogbo àwọn wundia yòókù lọ. Ọba gbé adé lé e lórí, ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣiti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si fẹràn Esteri jù gbogbo awọn obinrin lọ, on si ri ore-ọfẹ ati ojurere lọdọ rẹ̀ jù gbogbo awọn wundia na lọ; tobẹ̃ ti o fi gbe ade ọba kà a li ori, o si fi i ṣe ayaba ni ipò Faṣti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ésítà sì wu ọba ju àwọn obìnrin tó kù lọ, Ó sì rí ojú rere àti oore ọ̀fẹ́ gbà ju ti àwọn wúndíá tó kù lọ. Nítorí náà ó fi adé ọba dé e ní orí ó sì fi ṣe ayaba dípò Fásítì.