Esther 2:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó wà lára àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lẹ́rú láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ Babiloni pẹlu Jekonaya, ọba Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti a ti mu lọ lati Jerusalemu pẹlu ìgbekun ti a kó lọ pẹlu Jekoniah, ọba Juda, ti Nebukadnessari, ọba Babeli ti kó lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jérúsálẹ́mù, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jéóhákímù ọba Júdà.