Esther 2:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọba pàṣẹ, tí wọ́n kéde rẹ̀, tí wọ́n sì mú ọpọlọpọ wundia wá sí ààfin, ní Susa, ní abẹ́ ìtọ́jú Hegai, tí ń tọ́jú àwọn ayaba, Ẹsita wà pẹlu wọn ní ààfin ní abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati a gbọ́ ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀, nigbati a si ṣà ọ̀pọlọpọ wundia jọ si Ṣuṣani ãfin, si ọwọ Hegai, a si mu Esteri wá si ile ọba pẹlu si ọwọ Hegai, olutọju awọn obinrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Ṣúsà, sí abẹ́ ìtọ́jú Hégáì. A sì mú Ẹ́sítà náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hégáì lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin.