Esther 3:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n fi àwọn ìwé náà rán àwọn òjíṣẹ́ sí gbogbo agbègbè ọba pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Juu run, ati kékeré ati àgbà, ati obinrin ati ọmọde ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹtala oṣù kejila oṣù Adari, kí wọ́n sì kó gbogbo ohun ìní wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si fi iwe na rán awọn òjiṣẹ si gbogbo ìgberiko ọba, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo enia Juda, ati ọ̀dọ ati arugbo, awọn ọmọde, ati awọn obinrin ki o ṣegbe ni ọjọ kan, ani li ọjọ kẹtala, oṣù kejila, ti iṣe oṣù Adari, ati lati kó ohun iní wọn fun ijẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́ẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Ádárì kí a sì kó àwọn ohun ìní in wọn.