Esther 3:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n níláti sọ ohun tí ó wà ninu ìwé náà di òfin ní gbogbo ìgbèríko, kí wọ́n sì sọ fún gbogbo eniyan, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀ran iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo igberiko, lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki nwọn ki o le mura de ọjọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ mú àdàkọ kan ìwé náà kí a tẹ̀ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbéríko kí ó sì di mímọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà.