Esther 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn olóyè ní ẹnu ọ̀nà ààfin ọba a sì máa foríbalẹ̀ láti bu ọlá fún Hamani, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, ṣugbọn Modekai kò jẹ́ foríbalẹ̀ kí ó bu ọlá fún Hamani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, kunlẹ nwọn si wolẹ fun Hamani: nitori ọba ti paṣẹ bẹ̃ nitori rẹ̀. Ṣugbọn Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò si wolẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hámánì, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Modékáì kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún-un.