Esther 3:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ojoojumọ ni wọ́n ń kìlọ̀ fún un, ṣugbọn kò gbọ́. Nítorí náà, wọ́n lọ sọ fún Hamani, wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá ohun tí Modekai sọ ni yóo ṣẹ, nítorí ó sọ fún wọn pé Juu ni òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati nwọn wi fun u lojojumọ, ti on kò si gbọ́ ti wọn, nwọn sọ fun Hamani, lati wò bi ọ̀ran Mordekai yio ti le ri: nitori on ti wi fun wọn pe, enia Juda ni on.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún-un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hámánì nípa rẹ̀ láti wòó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Módékáì ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.