Esther 3:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó mọ̀ pé Juu ni, ó kà á sí ohun kékeré láti pa Modekai nìkan, nítorí náà, ó pinnu láti pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ eniyan Modekai run, ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si jẹ abùku loju rẹ̀ lati gbe ọwọ le Mordekai nikan; nitori nwọn ti fi awọn enia Mordekai hàn a: nitorina gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ijọba Ahaswerusi, ni Hamani wá ọ̀na lati parun, ani awọn enia Mordekai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Módékáì jẹ́, ó kẹ́gàn àti pa Módékáì nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hámánì ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Módékáì run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ṣérísésì.