Esther 3:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kejila ìjọba Ahasu-erusi, Hamani pinnu láti yan ọjọ́ tí ó wọ̀, nítorí náà, ní oṣù kinni tíí ṣe oṣù Nisani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ gègé tí wọn ń pè ní Purimu, níwájú Hamani láti ọjọ́ dé ọjọ́ ati láti oṣù dé oṣù, títí dé oṣù kejila tíí ṣe oṣù Adari.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li oṣù kini, eyinì ni oṣù Nisani, li ọdun kejila ijọba Ahaswerusi, nwọn da purimu, eyinì ni, ìbo, niwaju Hamani, lati ọjọ de ọjọ, ati lati oṣù de oṣù lọ ide oṣù kejila, eyinì ni oṣù Adari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kejìlá ọba Ṣérísésì, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù nísánì, wọ́n da Púrì (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hámánì láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Ádárì.