Esther 4:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní gbogbo agbègbè ati káàkiri ibi tí òfin ati àṣẹ ọba dé, ni àwọn Juu tí ń ṣọ̀fọ̀ tí wọn ń gbààwẹ̀ tẹkúntẹkún. Ọpọlọpọ wọn da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n sì da eérú sára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni gbogbo ìgberiko, nibiti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, ọ̀fọ nla ba gbogbo awọn Ju; ati ãwẹ, ati ẹkún, ati ipohùnrere; ọ̀pọlọpọ li o si dubulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ninu ẽru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní gbogbo ìgbèríko tí ikú àti àṣẹ ọba dé, ọ̀fọ̀ ǹlá dé bá àwọn Júù, pẹ̀lú ààwẹ̀, ẹkún àti ìpohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà ninú aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi eérú kúnra.