Esther 4:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹsita bá pe Hataki, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí ọba ti yàn láti máa ṣe iranṣẹ fún un. Ó pàṣẹ fún un pé kí ó lọ bá Modekai kí ó bèèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó fà á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Esteri pè Hataki, ọkan ninu awọn ìwẹfa ọba, ẹniti o ti yàn lati duro niwaju rẹ̀, o si rán a si Mordekai lati mọ̀ ohun ti o ṣe, ati nitori kini?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ẹ́sítà pe Hátakì, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún-un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Módékáì àti ohun tí ó ṣe é.