Esther 5:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu fún wọn bí ọrọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ tó, iye àwọn ọmọ rẹ̀, bí ọba ṣe gbé e ga ju gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn olórí yòókù lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hamani si ròhin ogo ọrọ̀ rẹ̀, ati ọ̀pọlọpọ awọn ọmọ rẹ̀, ati ninu ohun gbogbo ti ọba fi gbe e ga, ati bi o ti gbe on ga jù awọn ijoye, ati awọn ọmọ-ọdọ ọba lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hámánì gbéraga sí wọn nípa títóbi ọ̀rọ̀ rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ọ̀nà tí ọba ti bu ọla fún-un àti bí ó ṣe gbé e ga ju àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè tó kù lọ.