Esther 5:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hamani tún fi kún un pé “Ayaba Ẹsita kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá ọba wá sí ibi àsè rẹ̀, àfi èmi nìkan. Ó sì ti tún pe èmi ati ọba sí àsè mìíràn ní ọ̀la.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hamani si wi pẹlu pe, ani Esteri ayaba kò mu ki ẹnikẹni ki o ba ọba wá si ibi àse ti o ti sè bikoṣe emi nikan; li ọla ẹ̀wẹ li a si tun pè mi pẹlu ọba lati wá si ọdọ rẹ̀,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hámánì tún fi kún-un pé, “Kìí ṣe èyí nìkan. Èmi nìkan ni ayaba Ẹ́sítà pè láti sin ọba wá sí ibi àsè tí ó sè. Bákan náà, ó sì tún ti pè mí pẹ̀lú ọba ní ọ̀la.