Esther 5:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sereṣi iyawo rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un, pé, “Lọ ri igi tí wọn ń gbé eniyan kọ́, kí ó ga ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, sọ fún ọba pé kí ó so Modekai kọ́ sí orí igi náà. Nígbà náà inú rẹ yóo dùn láti lọ sí ibi àsè náà.” Inú Hamani dùn sí ìmọ̀ràn yìí, ó lọ ri igi náà mọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Sereṣi aya rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ wi fun u pe, Jẹ ki a rì igi kan, ki o ga ni ãdọta igbọnwọ, ati li ọla ni ki o ba ọba sọ ọ ki a so Mordekai rọ̀ nibẹ: iwọ̀ o si fi ayọ̀ ba ọba lọ si ibi àse. Nkan yi dùn mọ Hamani, o si rì igi na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyàwó rẹ̀ Ṣérésì àti àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ wí fún-un pé, “Ri igi kan, kí ó ga tó ìwọ̀n míta mẹ́ta-lélógún, kí o sì sọ fún ọba ní òwúrọ̀ ọ̀la kí ó gbé Módékáì rọ̀ sórí i rẹ̀. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọba lọ sí ibi àṣè pẹ̀lú ayọ̀.” Èrò yí dùn mọ́ Hámánì nínú, ó sì ri igi náà.