Esther 5:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó rí Ẹsita tí ó dúró ní ìta, inú rẹ̀ dùn sí i, ọba na ọ̀pá oyè tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí i, Ẹsita sì na ọwọ́, ó fi kan ṣóńṣó ọ̀pá náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe nigbati ọba ri ti Esteri ayaba duro ni àgbala, on si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀: ọba si nà ọ̀pá alade wura ti o wà lọwọ rẹ̀ si Esteri. Esteri si sunmọ ọ, o si fi ọwọ kàn ori ọpá alade na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó rí ayaba Ẹ́sítà tí ó dúró nínú àgbàlá, inú un rẹ̀ yọ́ síi, ó sì na ọ̀pá aládé wúrà ọwọ́ọ rẹ̀ sí i. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ́sítà ṣe ṣún mọ́ ọn ó sì fi ọwọ́ kan orí ọ̀pá náà.