Esther 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọn tí ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita léèrè pé, “Kí ni ìbéèrè rẹ Ẹsita, a óo ṣe é fún ọ, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ ni a óo jẹ́ kí ó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ títí dé ìdajì ìjọba mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun Esteri nibiti nwọn gbe nmu ọti-waini pe, kini ibere rẹ? a o si fi fun ọ: ki si ni ẹ̀bẹ rẹ? ani de idajì ijọba, a o si ṣe e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì, ọba tún béèrè lọ́wọ́ Ésítà, “Báyìí pẹ́: kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìwọ ń béèrè fún? Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọbaa mi, a ó fi fún ọ.”