Esther 6:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hamani lọ mú ẹ̀wù ati ẹṣin náà, ó ṣe Modekai lọ́ṣọ̀ọ́, ó gbé e gun ẹṣin, ó sì ń ké níwájú rẹ̀ bí ó ti ń fà á káàkiri gbogbo ìlú pé, “Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá lọ́lá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Hamani mu aṣọ ati ẹṣin na, o si ṣe Mordekai li ọṣọ́, o si mu u là igboro ilu lori ẹṣin, o si kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Hámánì ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ Módékáì, Módékáì sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájúu rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!”