Esther 6:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi, iyawo rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí Modekai, ẹni tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀ bá jẹ́ Juu, o kò ní lè ṣẹgun rẹ̀, òun ni yóo ṣẹgun rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hamani si sọ gbogbo ohun ti o ba a, fun Sereṣi obinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn enia rẹ̀, amoye, ati Sereṣi obinrin rẹ̀, wi fun u pe, Bi Mordekai ba jẹ iru-ọmọ awọn Ju, niwaju ẹniti iwọ ti bẹ̀rẹ si iṣubu na, iwọ, kì yio le bori rẹ̀, ṣugbọn iwọ o ṣubu niwaju rẹ̀ dandan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ síi fún Ṣérésì ìyàwóo rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀. Àwọn olùbádámọ̀ràn an rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún-un pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Módékáì ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubúu rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun!”