Esther 6:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba bèèrè pé irú ọlá wo ni a dá Modekai fún ohun tí ó ṣe yìí? Wọ́n dá a lóhùn pé ẹnikẹ́ni kò ṣe nǹkankan fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi pe, Iyìn ati ọlá wo li a fi fun Mordekai nitori eyi? Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba ti nṣe iranṣẹ fun u wi pe, a kò ṣe nkankan fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Módékáì ti gbà fún èyí?” Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tíì sí ohun tí a ṣe fún-un.”