Esther 6:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bèèrè pé, “Ta ló wà ninu àgbàlá?” Àkókò náà ni Hamani wọ inú àgbàlá ààfin ọba, láti bá ọba sọ̀rọ̀ láti so Modekai rọ̀ sórí igi tí ó rì mọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi pe, Tani mbẹ ni àgbala? Hamani si ti de àgbala akọkàn ile ọba, lati ba ọba sọ ọ lati so Mordekai rọ̀ sori igi giga ti o ti rì fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba wí pé, “Taa ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí Hámánì ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa ṣíṣo Módékáì lórí igi tí ó ti rì fún-un.