Esther 6:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí wọ́n kó wọn fún ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ, kí ó fi ṣe ẹni náà lọ́ṣọ̀ọ́, kí ó gbé e gun ẹṣin, kí ó sì fà á káàkiri gbogbo ìlú, kí ó máa kéde pé, ‘Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá a lọ́lá.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki a si fi ẹ̀wu ati ẹṣin yi le ọwọ ọkan ninu awọn ijoye ọba ti o lọlajùlọ, ki nwọn fi ṣe ọṣọ fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun, ki o si mu u gẹṣin là igboro ilu, ki o si ma kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí a fí aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn-ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn má a kéde níwájúu rẹ̀ pé, ‘Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!’ ”