Esther 7:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita pé, “Ẹsita, Ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, a óo ṣe é fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ, gbogbo rẹ̀ ni yóo sì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, àní títí kan ìdajì ìjọba mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si tun wi fun Esteri ni ijọ keji ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini pe, kini ẹbẹ rẹ, Esteri ayaba? a o si fi fun ọ: ki si ni ibère rẹ? a o si ṣe e, ani lọ ide idaji ijọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Ẹ́sítà ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọbaà mi, n ó fi fún ọ.”