Esther 7:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ti ta èmi ati àwọn eniyan mi fún pípa, wọn ó sì pa wá run. Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n ta tọkunrin tobinrin wa bí ẹrú lásán ni, n kì bá tí yọ ìwọ kabiyesi lẹ́nu rárá, nítorí a kò lè fi ìnira wa wé àdánù tí yóo jẹ́ ti ìwọ ọba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori a ti tà wa, emi ati awọn enia mi, lati run wa, lati pa wa, ki a le parun. Ṣugbọn bi o ṣe pe, a ti tà wa fun ẹrúkunrin, ati ẹrúbirin ni, emi iba pa ẹnu mi mọ́, bi o tilẹ jẹ pe ọta na kò le di ofò ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́. Bí a bá ti lẹ̀ tàwá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹbá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí.”