Esther 7:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ọba ti pada wá láti inú àgbàlá sí ibi tí wọ́n ti ń mu ọtí, ó rí Hamani tí ó ṣubú sí ibi àga tí Ẹsita rọ̀gbọ̀kú sí. Ọba ní, “Ṣé yóo tún máa fi ọwọ́ pa Ayaba lára lójú mi ni, ninu ilé mi?” Ní kété tí ọba sọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n faṣọ bo Hamani lójú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ọba pẹhinda lati inu àgbala ãfin sinu ibiti nwọn ti nmu ọti-waini, Hamani si ṣubu le ibi ìrọgbọkú lori eyi ti Esteri joko; nigbana ni ọba wi pe, yio ha tẹ́ ayaba lọdọ mi ninu ile bi? Bi ọ̀rọ na ti ti ẹnu ọba jade, nwọn bò oju Hamani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngán àsè náà, Hámánì ṣubú sórí àga tí Ẹ́sítà ayaba fẹ̀yìntì. Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?” Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hámánì lójú.