Esther 7:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Habona, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, bá sọ fún ọba pé, “Igi kan, tí ó ga ní aadọta igbọnwọ (mita 22) wà ní ilé rẹ̀, tí ó ti rì mọ́lẹ̀ láti gbé Modekai kọ́ sí, Modekai tí ó gba ẹ̀mí rẹ là.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Harbona ọkan ninu awọn ìwẹfa si wi niwaju ọba pe, Sa wò o, igi ti o ga ni ãdọta igbọnwọ ti Hamani ti rì nitori Mordekai ti o ti sọ ọ̀rọ rere fun ọba, o wà li oró ni ile Hamani. Ọba si wi pe, Ẹ so o rọ̀ lori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Háríbónà ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “igi tí ó ga tó ìwọ̀n mítà mẹ́talélógún (23 mítà) ni Hámánì ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilée rẹ̀. Ó ṣeé fún Módékáì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.” Ọba wí pé, ẹ ṣo ó rọ̀ sórí i rẹ́!