Esther 8:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ Ahasu-erusi ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Wọ́n fi rán àwọn iranṣẹ tí wọn ń gun àwọn ẹṣin tí wọ́n lè sáré dáradára, àwọn ẹṣin tí wọn ń lò fún iṣẹ́ ọba, àwọn tí wọ́n ń bọ́ fún ìlò ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Orukọ Ahaswerusi ọba li a fi kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀; o si fi iwe wọnni rán awọn ojiṣẹ lori ẹṣin, ti o gùn ẹṣin yiyara, ani ibãka, ọmọ awọn abo ẹṣin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Modékáì sì fi àṣẹ ọba Ṣéríṣésì kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán-an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba.