Esther 8:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Òfin náà fún àwọn Juu ní àṣẹ láti kó ara wọn jọ, láti gba ara wọn sílẹ̀, ati láti run orílẹ̀-èdè tabi ìgbèríko tí ó bá dojú ìjà kọ wọ́n, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn obinrin wọn. Wọ́n lè run ọ̀tá wọn láì ku ẹnìkan, kí wọ́n sì gba gbogbo ìní wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu eyiti ọba fi aṣẹ fun gbogbo awọn Ju, ti o wà ni ilu gbogbo, lati kó ara wọn jọ, ati lati duro gbà ẹmi ara wọn là, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo agbara awọn enia, ati ìgberiko na, ti o ba fẹ kọlu wọn, pẹlu awọn ọmọ wẹwẹ ati awọn obinrin ki o ṣegbe; ki nwọn ki o si kó ìni wọn fun ara wọn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn; láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀ èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbéríko tí ó bá fẹ́ kọ lù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn; kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀taa wọn.