Esther 8:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àkọsílẹ̀ yìí di òfin fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèríko, kí àwọn Juu baà lè múra láti gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn ní ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀ran inu iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo ìgberiko lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki awọn Ju ki o le mura de ọjọ na, lati gbẹsan ara wọn lara awọn ọta wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbéríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò leè múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀taa wọn.