Esther 8:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní gbogbo agbègbè, ati ní àwọn ìlú tí ìkéde yìí dé, ìdùnnú ati ayọ̀ kún inú àwọn Juu, wọ́n se àsè pẹlu ayẹyẹ, wọ́n sì gba ìsinmi. Àwọn ẹ̀yà mìíràn sọ ara wọn di Juu, nítorí pé ẹ̀rù àwọn Juu ń bà wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni olukulùku ìgberiko, ati ni olukuluku ilu nibikibi ti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, awọn Ju ni ayọ̀ ati inu-didùn, àse, ati ọjọ rere. Ọ̀pọlọpọ awọn enia ilẹ na si di enia Juda; nitori ẹ̀ru awọn Ju ba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú, ní gbogbo ibi tí àṣẹ ọba dé, ni ayọ̀ àti inú dídùn ti wà láàrin àwọn Júù, wọ́n sì ń ṣe àsè àti àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tó kù sọ ara wọn di Júù nítorí ẹ̀rù àwọn Júù bà wọ́n.