Esther 8:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó dìde, ó sì dúró níwájú ọba, ó ní, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, tí mo sì rí ojurere rẹ̀, bí ó bá fẹ́ràn mi, tí ọ̀rọ̀ náà bá tọ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí ìwé àṣẹ kan ti ọ̀dọ̀ ọba jáde, láti yí ète burúkú tí Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, pa pada, àní ète tí ó pa láti run gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní ìjọba rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi pe, bi o ba wù ọba, bi mo ba si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀, ti nkan na ba si tọ́ loju ọba, bi mo ba si wù ọba, jẹ ki a kọwe lati yí iwe ete Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi nì pada, ti o ti kọ lati pa awọn Ju run, ti o wà ni gbogbo ìgberiko ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojú rere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lúu mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hámánì ọmọ Hámédátà, ará Ágágì, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run.