Esther 8:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ahasu-erusi ọba dá Ẹsita Ayaba ati Modekai Juu lóhùn pé, “Mo ti so Hamani kọ́ sórí igi, nítorí ète tí ó pa lórí àwọn Juu, mo sì ti fún Ẹsita ní ilé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Ahaswerusi ọba wi fun Esteri ayaba, ati fun Mordekai ara Juda na pe, Sa wò o, emi ti fi ile Hamani fun Esteri; on ni nwọn si ti so rọ̀ lori igi, nitoripe o ti gbe ọwọ le awọn Ju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Ṣéríṣésì dá Ẹ́sítà ayaba àti Módékáì aráa Júù náà lóhùn pé, “Nítorí Hámánì kọ lu àwọn aráa Júù, èmi ti fi ilée rẹ̀ fún Ẹ́sítà, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi.