Esther 8:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọjọ́ kẹtalelogun oṣù kẹta, tíí ṣe oṣù Sifani ni Modekai pe àwọn akọ̀wé ọba, wọ́n sì kọ òfin sílẹ̀ nípa àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí Modekai ti sọ fún wọn. Wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn gomina, ati àwọn olórí àwọn agbègbè, láti India títí dé Etiopia, gbogbo wọn jẹ́ agbègbè mẹtadinlaadoje (127). Wọ́n kọ ọ́ sí agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, wọ́n sì kọ sí àwọn Juu náà ní èdè wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li a si pè awọn akọwe ọba li akokò na ni oṣù kẹta, eyini ni oṣù Sifani, li ọjọ kẹtalelogun rẹ̀; a si kọ ọ gẹgẹ bi Mordekai ti paṣẹ si awọn Ju, ati si awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati olori awọn ìgberiko metadilãdoje, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède wọn ati si awọn Ju gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi ède wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́ṣẹ̀ kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù sífánì. Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Módékáì sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóṣo baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tadínláàdóje tí ó lọ láti Ińdíà títí ó fi dé kúsì. Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn.