Esther 9:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹsita dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí á fún àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní sí àwọn ọ̀tá wọn ní ọ̀la, kí á sì so àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá rọ̀ sí orí igi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Esteri wipe, Bi o ba wù ọba, jẹ ki a fi aṣẹ fun awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani ki nwọn ki o ṣe li ọ̀la pẹlu gẹgẹ bi aṣẹ ti oni, ki a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀ lori igi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ́sítà sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.”