Esther 9:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa tún parapọ̀, wọ́n sì pa ọọdunrun (300) ọkunrin sí i. Ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹrinla oṣù Adari pẹlu, nwọn si pa ọ̃durun ọkunrin ni Ṣuṣani; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Ṣúṣà, Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn.