Esther 9:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní Susa, ọjọ́ kẹẹdogun oṣù ni wọ́n tó ṣe ayẹyẹ tiwọn. Ọjọ́ kẹtala ati ọjọ́ kẹrinla ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa pa àwọn ọ̀tá wọn, ní ọjọ́ kẹẹdogun, wọ́n sinmi, ó sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn Ju ti mbẹ ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹtala rẹ̀, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀; ati li ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati inu didùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ Kẹẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àṣè àti ayọ̀.