Esther 9:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdí nìyí tí àwọn Juu tí wọn ń gbé àwọn agbègbè fi ya ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari sọ́tọ̀ fún ọjọ́ àsè, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn Ju ti o wà ni iletò wọnni, ti nwọn ngbe ilu ti kò li odi, nwọn ṣe ọjọ kẹrinla oṣù Adari li ọjọ inu-didùn, ati àse, ati ọjọ rere, ati ọjọ ti olukulùku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ni àwọn Júù-tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àṣè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn.