Esther 9:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn Juu gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ìbànújẹ́ ati ẹ̀rù wọn di ayọ̀, tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn sì di ọjọ́ àjọ̀dún. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àjọ̀dún ati ayọ̀, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn, tí wọn yóo máa fún àwọn talaka ní ẹ̀bùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ọjọ lọwọ eyiti awọn Ju simi kuro ninu awọn ọta wọn, ati oṣù ti a sọ ibanujẹ wọn di ayọ̀, ati ọjọ ọ̀fọ di ọjọ rere; ki nwọn ki o le sọ wọn di ọjọ àse, ati ayọ̀, ati ọjọ ti olukuluku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀, ati ẹbun fun awọn talaka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àṣè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní.