Esther 9:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Hamani, ọmọ Hamedata, láti ìran Agagi, ọ̀tá àwọn Juu ti pète láti pa àwọn Juu run. Ó ti ṣẹ́ gègé, tí wọn ń pè ní Purimu, láti mọ ọjọ́ tí yóo pa àwọn Juu run patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pe, Hamani ọmọ Medata, ara Agagi nì, ọta gbogbo awọn Ju ti gbiro lati pa awọn Ju run, o si ti da Puri, eyinì ni ibo, lati pa wọn, ati lati run wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Hámánì ọmọ Hámédátà, aráa Ágágì, ọ̀ta gbogbo àwọn Júù, ti gbérò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di Púrì (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìṣọdahoro àti ìparun wọn.