Esther 9:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba, ọba kọ̀wé àṣẹ tí ó mú kí ìpinnu burúkú tí Hamani ní sí àwọn Juu pada sí orí òun tìkararẹ̀, a sì so òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sórí igi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati Esteri tọ̀ ọba wá, o fi iwe paṣẹ pe, ki ete buburu ti a ti pa si awọn Ju ki o le pada si ori on tikalarẹ̀, ati ki a so ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sori igi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Ẹ́sítà sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hámánì ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí oun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi.