Esther 9:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn olórí àwọn agbègbè, àwọn baálẹ̀, àwọn gomina ati àwọn aláṣẹ ọba ran àwọn Juu lọ́wọ́, nítorí pé ẹ̀rù Modekai ń bà wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn olori ìgberiko, ati awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati awọn ti nṣe iṣẹ ọba, ràn awọn Ju lọwọ, nitori ẹ̀ru Mordekai bà wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbéríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Módékáì.