Esther 9:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n kọ ìwé sí gbogbo àwọn Juu ní gbogbo agbègbè mẹtẹẹtadinlaadoje (127) tí ó wà ninu ìjọba Ahasu-erusi. Ìwé náà kún fún ọ̀rọ̀ alaafia ati òtítọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju, si ẹtadilãdoje ìgberiko ijọba Ahaswerusi, ọ̀rọ alafia ati otitọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Módékáì sì kọ ìwé ránsẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbéríko mẹ́tadínláàdóje (127) ní ilé ọba Ṣéríṣésì ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀