Esther 9:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
pé wọn kò gbọdọ̀ gbàgbé láti máa pa àwọn ọjọ́ Purimu mọ́ ní àkókò wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Modekai ati Ẹsita Ayaba pa fún àwọn Juu, ati irú ìlànà tí wọ́n là sílẹ̀ fún ara wọn ati arọmọdọmọ wọn, nípa ààwẹ̀ ati ẹkún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati fi idi ọjọ Purimu wọnyi mulẹ, li akokò wọn ti a yàn gẹgẹ bi Mordekai, ara Juda, ati Esteri ayaba ti paṣẹ fun wọn, ati bi nwọn ti pinnu rẹ̀ fun ara wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ọ̀ran ãwẹ ati ẹkún wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ọ Púrímù yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Módékáì àti Ẹ́sítà ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò ààwẹ̀ àti ẹkún un wọn.