Exodus 1:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, wọ́n yan àwọn akóniṣiṣẹ́ láti ni wọ́n lára pẹlu iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n lò wọ́n láti kọ́ ìlú Pitomi ati Ramesesi tíí ṣe àwọn ìlú ìṣúra fún Farao.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni nwọn ṣe yàn akoniṣiṣẹ le wọn, lati fi iṣẹ wọn pọ́n wọn loju. Nwọn si kọ́ ilu iṣura fun Farao, Pitomu ati Ramesesi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pítómi àti Ráméṣéṣì gẹ́gẹ́ bí ìlú ìkó ìṣúra pamọ́ sí fún Fáráò.